Document Details

TransparentEarthArt

Uploaded by TransparentEarthArt

Federal University Oye Ekiti

Tags

literature analysis drama Nigerian culture

Full Transcript

IGINLA'S HOUSE Iginla so fun iyawo e wipe omokunrin kan fun ohun lowo ni Ado-Ekiti, inkan ti ohun ri niwaju e, ohun kan so die fun nitori wipe ohun ri okan e wipe ko gba ohun gbo. Sugbon mo so fun wioe ko fun P.A. mi ni phone number e. IYAWO IGINLA: Kini inkan ti Olorun ba yin so nipa e. IGINLA:...

IGINLA'S HOUSE Iginla so fun iyawo e wipe omokunrin kan fun ohun lowo ni Ado-Ekiti, inkan ti ohun ri niwaju e, ohun kan so die fun nitori wipe ohun ri okan e wipe ko gba ohun gbo. Sugbon mo so fun wioe ko fun P.A. mi ni phone number e. IYAWO IGINLA: Kini inkan ti Olorun ba yin so nipa e. IGINLA: Ekini; ile to wa ni egbe lapa osi, ota lop ngbe nibe. Ekeji; Eni to wa niwaju e, ohun pero ati paa danu sugbon mo ti gbadura fun ko maa bale ri pa Eketa; Kii se nkan ti o nro si awon adugbo ni awon adugbo nro si Ekerin; Mori wipe igba to fi chairman adugbo sile, won tun fun ni chairman miran Ikarun; Ibi kibi to ba de, he should do whatever he's asked to do Ikeje; I also saw that God has approved a duplex for him. IYAWO IGINLA: Ehn Ehn IGINLA: He is a leader, that is how God created him IYAWO IGINLA: Sebi eni phone number e wa ni owo P.A. IGINLA: Benii IYAWO IGINLA: E pe, ke so gbogbo e fun ki okan yin bale fuye, ati wipe ki o ba le sora se lodo awon eniyan buruku wonyii IGINLA: Mo ma sofun sugbo kole gbamigbo nitori oore nla nla to ti se ninu aye won, ero okan re maje pe ogun to nle won lo fe ki ohun ko eyin si won. IYA OLOWO ATI ORE ADEBAYO Adebayo's friend went to meet Iya Olowo when he heard that she went to report Adebayo to his boss, the Accountant General that she wants to collect her money. ORE ADEBAYO: E kasan ma, oro ore mi Adebayo ni mo fe ri yin fun,nipa oro owo IYA OLOWO: Woo, so fun ore e wipe ti ko ba funmi ni owo mi, kekere ni mo si fi oju e ri lodo Accountant General. Ko sofun, emi ni lawyer Ondo state governor ati egbon iyawo governor Ekiti state, omo oba Ife naa si nimi pelu, mo mo eyan gan. Se won lo ni agbara ni, gbogbo awon ti mo daruko wonyii kole baa ku. Ise yen ma bo lowo e ORE ADEBAYO: Won fun mi ni number omo yin, mo sip e, lo wa salaye fun mi wipe awon to n Adebayo sise lowa bayin nile peke paro moo. Awon to de wa bayin yii, won jo pin owo naa ni IYA OLOWO: Ko kan mi o. ko did a owo mi pada ni mo wa after ORE ADEBAYO: Se epe gbogbo won po lati mo ooto oro. Ki eto gbe igbese. IYA OLOWO: E lo so fun ore yin, ki eyin gan ba wa ninu owo naa, laije bee. Haaaaaa, wahala maa wa. Gbogbo agbara ti mo ba ni ni ma fi ba ja ORE ADEBAYO PELU CHIEF ALAORO Nigba ti gbogbo oro doju e, ore Adebayo loba chief Alaoro fun ona abayo nile babalawo CHIEF ALAORO: Gbogbo alaye e yin ni mo gbo, mo siti se iwadi nipa e, Adebayo ti seleri pr ohun maa da 500k pada nipari osu kerin loju Accountant General. E loso fun wipe ko gbodo da owo Kankan pada, ti ko ba fe ki aye fi ohun sesin, ki o maa ko ara e si wahala nla ti owo e ko nika ORE ADEBAYO: Kini itumo inkan ti e nso sir CHIEF ALAORO: Se eri 2m yii lo mu ayipada rere ba ore yin. Ayipada rere to ba ore yin lo mu iwosan de ba obinrin yii, eniyan to le gan ni obinrin yii, ise owo re yii lo fa ifaseyin, aisan ati orisirisi inkan sinu aye e. Osi ti setan lati ba aye ore e je sugbon olorun maa ja fun ore e ORE ADEBAYO: Ase oo, Baba. CHIEF ALAORO: Eje ki o lo fi ejo sun Ooni Ife, kolo so fun Governor Ondo state ati gbogbo agbara to ba ni. Ki e si kilo fun ko ma da owo naa pada nitori olewu o. Ti won ba ti da owo yii pada, aisan to nse obinrin yii maa pada si lara, ati awon nkan miran bi ajalu, nigbati won ba n wadi si, owo ore e fun rara e ni won maa ba nibe, nitori owo to bad a pada lo faa ORE ADEBAYO: Kini ki ore mi wa se CHIEF ALAORO: O ma se suru ni ko je ki Ooni ma fa ohun, Ondo state Governor ati awon yooku maa faa ORE ADEBAYO: Chief, ore mi yii ko le pe retire lenu ise ijoba, ohun lo fa ti eru fi nba. Nitori igba ti mo ni isoro, ohun lo duro timi, ohun yii na loba mi san gbogbo owo ile iwe awon omo mi. ko kan je kin mo isoro naa lara rara. CHIEF ALAORO: Emi ti ri gbogbo e, awon to ngbogun ti po gan. ORE ADEBAYO: Looto ni sa, e jana, awon kan lo fun lowo ni ibi ise e ti won fe fi koba lai bere owo lowo won rara, awon kan na lotun pe ipade si ministry of finance lati koba sugbon Olorun ko yo. Church to nlo gan, won tun set e up ni be amoo pakute yen mu elomiran CHIEF ALAORO: Ijoko to n joko si ni ibi ise e,orisirisi inkan ni won tii gbe sori ijoko ohun sugbon Olorun ko yo. Idi ti won de fi se gbogbo ise ise buruku yii ni wipe awon wonyii ri pe ebun kan nbo niwaju e. Ohun na se fe ba oruko re je tabi ki won fi aisan da wo soju kan. Ile gan to n gbe, won lo ju oogun sibe fun omo ati iyawo sugbon Olorun ju won loo. Asedanu ni won nse. Gbogbo won kan n binu ori lasan ni. BABALAWO ATI ORE ADEBAYO Babalawo kan pe ore Adebayo wipe ohun fe ri, ati wipe ohun ni oro ti ohun fe ba so nipa isoro ti ore e nla koja, ni won ba fii ipade si joint beer parlor BABALAWO: Eyin lore Adebayo ORE: Yes BABALAWO: Eni kan lo fun mi ni phone number yin ORE: Se ko si inkan kan oo BABALAWO: Inkan kan wa, mo fe ki e bami be, ko dariji mi, won ni eyin nikan lo mo oju e dada ORE: Ki lo sele gangan BABALAWO: Awon adugbo lo gbe ise wa fun mi kin ba won so ore yin di idakuda sugbon ise naa yii mo mi lowo ORE: Bi ti bawo ati wipe, kini won ni o fi se won, kini ese ti won lo se won BABALAWO: Ekini; won sope o se inkan si owo ti won fe fi se ona adugbo lati gba kadara won. Igba ti adugbo fe fa ona. Engineer ti won pe wa sope ohun ma gba 800k, awon adugbo si so wipe ko si ibi ti won ti maa ri owo, o wa seleri fun won pe ohun ma gbe 400k sile, to sigbe sile looto, ko pe si lo ra motor, to tun ko duplex. Awon adugbo wa so pe, gbogbo eniyan to ba ti gba ori ile ti won fa naa lo n gba kadara e. Ekeji; otun se birthday fun omo e lati gba kadara gbogbo awon omo wewe adugbo fun omo tie,won wa nipe kin ba won so omo e da inkan miran ko maaa lo si ile iwe bi eni ti kolo. Eketa; won sope ofe ki won maa fi oruko ohun pe adugbo, nitori oruko e nikan ni won da ni gbogbo adugbo Ekerin; won tun nipe o ma nko awon olopa wa si adugbo, wipe ko je ki eni kan kanle soro rara, laise omo onilu, ajoji lasan lasan Ekarun; nise lo n se bi oba ladugbo, won sope o fi gbogbo ile se cae park, ko je ki won ri ogo won lo Ekefa; won gbe ebo wa si iwaju ile e. O mu ebo naa, o jo danu leyin ti o jo, ebo naa wa pada sori eni to gbe ebo naa sibe,ni enikan wa mu eni ti o gbe ebo naa wa si odo mi. ORE: Ki lo wa sele lehin e, se eri naa toju BABALAWO: Oro itoju yen gan ni mo bawa. Ejoor, eba mi be ore yin fun idariji ORE: Idariji kini BABALAWO: Iwai ka ti mo si Adebayo ati idile e ORE: Iru iwa ika wo BABALAWO: Lati jewo agbara ti mo ni ti mo si fi jogun lodo baba nla mi. I. Mo koko ran eku emo tako tabo si ile e, mi ori abo eku naa amo inkan ti eku naa ba tii nse naa ni ohun ati iyawo maa se, ti won ba nja, Adebayo ati iyawo e naa mama ja, sugbon ko ri be, lo ba mu ki n gbe igbese miran. II. Mo tun ran okete si inu ile won lati lo gbe ogun wo ile won sugbon se ni awon omo e pa okete naa ti won sun je. Nigbati iroyin kan mi lara ohun to sele si inkan to mo ran III. Ibinu ni mo filo gbe igbese ako, awon adugbo mu mi lo si new site e ti mo ko awon agbagba lo sibe lati lo se ise buburu si ibe dee sugbon gbogbo nkan ti won se, pabo lo ja si ORE: Hmmmm, gbogbo e patapata ni mo si yato si iketa. Ore mi fun rara e lo pa eku emo won yen danu to kosi inu iwo fence. See wa ri okete, bo se fe pa ni igi lo ba Plasma tv e to si fo, ohun lo se so fun awon omo e kin won lo sun. BABALAWO: Igba ti mo gbo wipe o ti ko losi new site to sun ibe moju ti ko si inkan to sele, eruba mi, lati le ri daju, mo losibe amoo aja bere si ni ngbo osi lemi. Okan mi o wa bale moo, iya wa n je mi, mo fe ki e bami baa soro ko mu mi lo sodo T.B. Joshua nitori iwadi fi han pe ohun ni ko je ka ri pa. ORE: O possible ko je ni ko je ki won rii pa nitori Ado lo ti lo n josin ni synagogue losoose, igba kan gan, ajijo ma n lo josin nibe nii ati okunrin to wa ni iwaju ile e BABALAWO: Eehhh eehhh, kile soo, okunrin iwaju ile e kee, okunrin yii gan gan ni olori ota e. ORE: Adebayo naa mo, sebi igba ti o gbo nkan ti arakunrin yi so nipa e lo ba ni wipe ko jeki won lo bura ni Aafin Ewi, leru baa to lo ko gbogbo agbagba adugbo joo ki won ba ohun be ore mi. Okunrin kan yii na lo le gbogbo alejo(tenant) ile e lo to so oro ti ko da nipa ore mi fun won. Ore mi sii ma n ran okunrin yii lowo o ati iya arugbo ti owa ni egbe ile e. I. Osoosu lo maa fun iya yen lowo fun oogun(drug) II. Okunrin iwaju ile e, igba ti ise bo lowo e, ohun lo ba wa ise ijoba pada III. Ohun lo nran lowo lati san owo ile iwe awon omo BABALAWO: Ha ha, aye male o. ORE: Gbogbo asiri won yen lo tu si lowo nigba ti oko kuro ni adugbo. Ni ti adugbo, awon inkan to se si adugbo yen ti poju I. O gbe 400k sile lati fi grade ona adugbo II. O gbe oloselu wa si adugbo lati gba owo lowo won III. Eksda project ohun lo mu wa ohun lo tun san 800k owo counterpart fund IV. Block pole merin lora fun won ati 20 poles V. O gba olopa si adugbo lati maa ba won patrol VI. 50k lo fi ra cable si adugbo melo lafe so VII. Ise kan wa ti ifa so wipe ki o se lodo araba to ba le se pe eeyan metala lo ma ku, omo iya e meji lo wa ninu won sugbon ko se. BABALAWO: Araba wo ninu won ORE: Araba Yesufu of Ado Ekiti BABALAWO: Se won mo ra won ni ORE: Daada, won close gaani BABALAWO: Otida, ma loba Araba ko ba mi baa soro, bo ti se ma mu mi lo si synagogue ati ki o dariji mi ORE: O better CHIEF ALAORO ATI ORE ADEBAYO PT 2 Adebayo's went to meet Chief Alaoro to tell him that government wants to give him a car a week ago in an event but he was scared to go because he was asked to bring his personal file along. So he was thinking they might want to dismiss him because of the woman that threatened him about the money matter. ORE ADEBAYO: Ni inkan bi ose kan seyin, governor fe gbe motor fun ore mi because of his good record with this present government CHIEF: Se bi mo soro nipa gift ni igba ti o koko wa, titori motor yii ni won se fe ba aye e je patapata, ohun lo fa gbogbo isoro to ni, to ba je wipe o gba motor naa, inu wahala ni iba wa bayi, eje ka fi gbogbo e dupe lowo olorun nitori oore to mu ibanuje dani ni, awon kan ti mo saaju, to yee ki won so fun, ti won je ore, se ni won lo ra waini ti won lo se ise buruku si ni occultic shrine, waini naa si wa ni shrine bo mo se soro yii ORE: Ha ha, ki le n so CHIEF: Won ba ti jo motor naa ati gbogbo ile ati inkan ini e ORE: Bi ti bawo CHIEF: Waini oran yen ni won fe fi taa lore amoo ni gbati won gbe fun tan, inu motor lasan lo gbe si nitori ko le mu, awon kan lori ninu motor e, ti won gbe ti won fe fi we motor, lehin ti won ba mu tan naa ku danu, awon ara ilea won won yen lo wa jo motor ati ile e. Olorun mo bi o se n se ise e. ORE: Oluwa ose oo CHIEF: Mori pe ire e wa lowo Governor to kogba sugbon ko se fun ORE: Ire e wa lowo Governor to wa ni ori oye ati Governor to kogba sile CHIEF: Beeni, toba wu won ki won je. Ko de si bami so fun ore e pe to bati retire, ko ma se mistake lo ki won ni office ibi to ti retire, nittori akoba, awon wonyii ko dehin lehin e after retirement amoo so fun pe ko farabale nitori eleda awon to se loore wa lehin e. Won n ja fun gann ORE: Ni igba to ko ile e tuntun,awon kan lo ba wipe kilo wa nidi oore to unse CHIEF: Oro po nidi e, gbogbo won to bere oro naa lowo e, ise buburu ni gbogbo won se si ile e lehin e pe ko nigbe inu ile hun ati wipe oku e lo maa gbe ibe tabi ki isoro de ba amo ki lo wa fid a won lohun ORE: Ose alaye fun won wipe igba ti ohun gba ise ijoba, elomiran ni won fe gba sugbon mistake ni won fi mu oruko e. eniyan ti won fe gba si se n je Falaye Akinleye Gabriel ohun naa n je Falaye Adebayo Zaccheaus. Igbati commissioner so wipe ki won lo ba ohun mu Falaye wa, form ti e ni won koko ri. Won gbi yan ju lati da duro sugbon ko sese, ose alaye pe igba yen ni ohun ti ba eleda ohun je eje pe gbogbo eniyan to ba ti nilo iranlowo ohun lo maa se fun ti agbara ohun ba ti ka. CHIEF: Ileri yen lo wa muse bayi ti gbogbo won n ro wipe kadara won lo fi n gba.

Use Quizgecko on...
Browser
Browser